Odu Ifa Eji Ogbe
Dia fun Akinlaja
Ti omo araye yoo maa yosuti sii
Won nike o rubo
O gbebo o rubo
O ni E se maa yosuti eyin lo
Egan o pe k’oyin ma dun
Suti le yo si mi
Ni mo fi lowo lowo
Ni mo fi bimo le mole
Ni mo fi bimo le omo
Ni mo fi ni ire gbogbo
E se maa yosuti eyin lo
Egan o pe koyin ma dun
Ase Ase Ase se ooo