Заклинание на открывшееся предсказание на ситуацию
Oyeku meji ire ooo
Akinlaja wi ibà
Mi iba
Mi iba orisa l’orisa fi dáji
Akinlaja l’óun w’oréré ayé
Ó ni talo nyo akápo omo t’oun lénu?
Wón ni igba omo eku le t’ojo?
Wón ni igba omo eku won ò leè t’ojó
Gbogbo omo eku tó nbá ebiti i yan odi
Ebiti ni yóó réyin won tán porogodo
Akinlaja wi ba
Mi iba
Mi iba orisa l’orisa fi dáji
Akinlaja l’óun w’oréré ayé
Ò ni taló nyo akápo omo t’òun lénu?
Wón ni igba omo eja ló nyo akápo omo tire lènu
Ó ni igba omo eja le t’ojo
Tabi wón o leè t’ojo?
won ni igba omo eja won ó leè t’ojo
Gbogbo omo eja tó n bá ìgèrèé yan odi
Ate ni yóó réyin won tán porogodo
Akinlaja wi iba
Mi iba
Mi iba orisa l’oun w’oréré ayé
Ó ni taló nyo akápo omo t’oun lénu?
Wón ni igba omo eran ló nyo akápo omo t’oun lénu
O ni igba omo eran le t’ojo?
Tabi won o lee t’ojo?
Won ni igba omo eran won o lee t’ojo
Gbogbo omo eran tó nbá ilasa a yan odi
Ilasa ni yóó réyin won tan porogodo
Dia fun Akinlaja
Baba nbe láarin otá
Ó nfojoojúmo kominú Ogun
Ebo ni wón ni kó wáá se
O gb’ebo, o ru’bo
Ase Ase Ase se ooo